• Home
  • Media
  • Languages
  • Free Stuff
  • Contact Us

Lessons in:
  • English
  • Français
  • Hausa
  • Yoruba

PostHeaderIcon KINI IGBALA ATI BAWO NI ENIYAN SELE NI ?

PostAuthorIconWritten by Biodun Owoladi | Print | E-mail

A ni ohun pupo lati se akiyesi nipa igbala ati bi a tise le ni, nitori ogunlogo eniyan ni ko mo ohun ti nje igbala. Opolopo ni ko mo iyato larin igbala ti ara ati igbala okan. Opolopo ko si mo iyato larin igbala okan ti Olorun nfi fun awon eniyan lori ile aye yi ati iye ainipekun – Luke 19:10; Heb 5:9.

Beni Olorun si nfe ki gbogbo eniyan ki oni igbala yi – I Tim. 2:4


1.       KINI A NPE NI IGBALA?

Igbala ni yiyo kuro ninu iponju, egbe tabi iparun. Eniti o ba si yo eniyan kuro ninu nka wonyi ni a npe ni Olugbala.

2.       IGBALA LABE MAJEMU LAILAI- IGBALA TI ARA

Igbala ti ara nikan ni awon omo Israeli ni labe Majemu Lailai. Olorun gba awon omo Israel la lowo Ogun Farao-Ex. 14:10-31. Awon omo Israel bebe fun Igbala ni igba iponju-Isaiah 33:2. Igbala ti Okan je ti iye ainipekun- Matt. 16:26.

3.       IGBALA LABE MAJEMU TITUN – IGBALA OKAN ENIYAN

Igbala kuro ninu ese tabi Idariji ese ni Igbala labe Majemu Titun-“… Yo gba awon eniyan re la kuro ninu ese won – Matt. 1:20-21; Luku 1:77

Ese ni aisan ti Emi ti omba gbogbo eniyan ja, ti o ya gbogbo eniyan kuro lodo Olorun. “Sugbon aisedede yin ni o ya yin kuro lodo Olorun…” Isaiah 59:1-2; Rom. 3:23”; ti o si mu iku, egbe ari iparun ayeraye ba eniyan, “…Nitori Iku ni ere Ese… Rom. 6:23.

Nigbati a ba nso nipa Igbala labe Majemu Titun ti Bibeli a nso ti irapada okan eniyan, idalare lodo Olorun Alaaye ati lati le ni ireti iye ainipekun “…Yio we eeri Okan yin nipa Eje Kristi Lati le sin Olorun A’laaye”- Heb. 9:14.

“…O wa di orisun Igbala ainipekun fun gbogbo awon ti ngbo tire”-Heb. 5:9.

4.       BAWO NI ENIYAN TI SE LE NI ANFANI IGBALA YI?

Olorun ni o seto ona Igbala yi fun eniyan lati mu eniyan pada sodo Ara re nipase JESU KRISTI- Jn. 14:6; Jn. 17: 2-3.

i.          Nipa Ife Olorun si Araye: Nitori olorun fe araye to bee ge, ti ofi Omo bibi Re kan soso fun ni, ki enikeni ti o ba gbaagbo, ki o ma ba segbe, sugbon ki ole ni iye ainipekun-Jn 3:16-18; Rom. 5:8

ii          Nipase Jesu Kristi; Opolopo awon eleri ti a ka oro won ninu bibeli lo mu kio daniloju pe ninu Jesu Kristi nikansoso ni Olorun ti pari ohun gbogbo ti ise ti Igbala okan gbogbo eniyan. Eniyan ko le ni igbala yi nipase elomiran –Ise Awon Aposteli 4:10-12.

  1. Eri Angeli Olorun; “…Jesu ni iwo o pe Oruko re nitori oun ni yo gba awon eniyan re la kuro ninu ESE won” Matt. 1:20-21; “…Nitori a bi OLUGBALA fun yin loni, ni ilu Dafidi, ti ise Kristi Oluwa”- Luku 2:10-11.
  2. Eri Johanu baptisi: Ni ijo keji Johanu ri Jesu mbo wa sodo re, o si wipe “Woo, odoaguntan Olorun, eniti o ko ese aye lo”- Jn 1:29.

c.         Eri Jesu Kristi: “Nitori Omo Eniyan (Jesu) de lati wa awon ti’o nu kiri ati lati gba won LA”. Luk. 19:10… Omo Eniyan (Jesu) li agbara li aye lati dari ese yin ji ni. Matt. 9:6, “… E o ku ninu ese yin, nitoti bikosepe e ba gbagbo pe, Emi ni (Jesu), e o ku ninu ese yin” -Jn 8:24.

d.         Eri Awon Aposteli: “Oun (Jesu) ni gbogbo awon Woli jeri sip e, nipa Oruko re (Jesu) li enikeni ti o ba gbaagbo, yo ri Imukuro ese gba Ise 10:38-43. “…Ko si si IGBALA lodo elomiran, nitori kosi Oruko miran labe Orun ti a fifun ni ninu eniyan, nipa eyiti a le fi gba wa la Ise 4:10-12.

5.       BAWO NI MO TI SE LE NI IGBALA NA?

Asiro awon Eniyan Nipa Igba Okan:

a.         Opolopo eniyan nso wipe, o di igbati a ba de orun ki a to mo eniti o ma ni Igbala. Sogbon Bibeli koni pe, “…Nisisiyi ni akoko itewogba Kiyesi, nisisiyi ni ojo Igbala” - II Kor. 6: 2.

b.         Awon elomiran so wipe, nitoripe awon ngbe igbe-aye rere ni awon fi ni igbala. Sugbon Bibeli koni pe, “Ore-ofe li a fi gba wa la nipa Igbagbo, ki isenipa ise, kia ma ba sogo-Efesu 2:8-9; Rom. 6:4.

c.         Awon elomiran so wipe, lori ikunle adura ni Olorun ti gbokan won la. Sugbon Bibeli koni pe, “…Eniti o ba gbagbo tia ba si baptisi re ni yo la”- Mark 16:15-16.

e.         Awon elomiran ro wipe awon Omo owo ati agbalagba ti won nse isami fun dipo Iribomi laimo ohun ti igbagbo je le ri Igbala. Sugbon Bibeli koni pe, “Nje nipa gbigbo ni igbagbo ti iwa ati gbigbo nipa Oro olorun’ -Rom. 10:17. “Eniti o ba gbagbo ti a ba si baptisi re yo la, sugbon eniti ko ba gbagbo yio jebi”- Mark 16:16.

Awon ohun merin ti Bibeli Palase lati se lati le ri Igbala Okan ninu Kristi

i        Igbagbo Ninu Jesu Kristi Nikan: Igbagbo ninu Jesu sinmi lori nkan meta pataki. O ni lati gba Jesu Kristi gegebi:

a. Omo Olorun – “Nitori Olorun fe araye tobe ge, ti o fi Omo bibi Re kansoso fun ni, ki enikeni ti o ba gbagbo ma ba segbe sugbon ki o le ni Iye ainipekun”…Jn 3:16-18, 36. “Sugbon iye awon ti o gbaa, awon li o fi agbara fun lati di Omo Olorun…”-Jn 1:12.” “Sugbon li aisi Igbagbo, ko se ise lati wu Olorun…” Heb 11:6.

b. Olugbala Re – “Nitori Olorun ko ran Omo re si aye lati da araye lejo, sugbon ki a le ti ipase Re gba araye la”. Jn 3:17; Lk 19:10, “Eniti Olorun ti gbe kale lati je etutu nipa igbagbo ninu Eje Re… “Rom. 6:23-25

c. Oluwa Re – Eyi ni Oludari tabi alakoso eyiti o ku igbe aye re. “… Olorun tifi Jesu na ti eyin kan mo Agbelebu je Oluwa ati Kristi”- Ise Awon Aposteli 2:36. ”…Eyiyi li ayanfe omo MI, eniti inu mu dun si gidigidi, e ma gbo tire”. Matt. 17:5.

ii       Ironupiwada Ese

Oni lati mo ara re ni elese “Otito li oro na, o si ye fun itewogba pe Kristi Jesu wa si aye lati gba elese la ninu awon eniti emi je Pataki”- ITim 1:15. Ki o ni ibanuje fun ese gbogbo ti o ti da-“Nitoripe ibanuje eni iwa bi Olorun a ma sise Ironupiwada si Igbala ti ki imu abamo wa… “II Kor. 7:10, ki o si pinnu lati ko ese sile- “Nitorina, eronupiwada, Ki e si tun yipada, ki a le pa ese yin re, ki akoko itura ba le ti iwaju Oluwa wa”-Acts 3:19, 17:30-31.

iii.      Ijewo Igbagbo ninu Kristi Jesu

O ni lati le fi enu ara re jewo Igbgbo re ninu Kristi Jesu lai tiju. “Pe, bi iwo ba fi enu re jewo Jesu li Oluwa, ti iwo si gbagbo li okan re pw Olorun ji I dide kuro ninu oku, a o gba o la. Nitori okan li a fi igbagbo si ododo, enu li a si fi ijewo si igbala” Rom. 10: 9-10, Ise Awon Aposteli 8:36-37. Nitori Olorun nfe ki o je eniti nwibe ti osi nsebe pelu - Matt. 5:37.

iv       Baptisimu

Iribomi ni Bibeli pe ni baptisimu “Bi a ti sin yin po pelu Re ninu baptisimu”… Kol. 2:12. Igboran si ase Jesu Kristi ni baptisimu, “…ki e si ma baptisi won li oruko Baba ati ni ti Omo ati ni ti Emi Mimo” Matt. 28:18-19.

Nigbati enikan ba gba Jesu Kristi gbo ti o si se ironupiwada ese re pelu ipinnu lati ko ese sile, O gbodo se baptisimu (Iribomi) ki o to le di eni-Igbala tabi gba Idariji ese re ninu Eje Kristi: “Peteru si wi fun won pe, eronupiwada, ki a si baptisi olukuluku yin li oruko Jesu Kristi fun idariji ese yin, eyin o sigba ebun Emi Mimo” -Ise Awon Aposteli-2:38, “…Dide ki a si baptisi re, ki osi we ese re nu, ki o si ma pe Oruko Oluwa” Ise 22:16 Jesu Kristi so wipe, “Eniti o ba gbagbo ti a ba si baptisi re, yo la…Mk. 16:16.

Lehin ti eniyan ba se baptisimu (Iribomi)ni Olorun mbere Otun iwa lowo re, “Nje a fi baptisimu sinu iku sin wa po pelu Re, pe gegebi a tiji Kristi dide kuro ninu oku nipa Ogo Baba, beni ki awa pelu ki o ma rin li otun iwa” Rom. 6:3-4.

Eniyan gbe Kristi wo tabi di Kristiani lehin ti o ba se Igboran baptisimu”. Nitori iye eyin ti a ti baptisi sinu Kristi ti gbe Kristi wo”. Gal. 3:26-27.

Baptisimu kanna ti eniyan se fun Idariji ese ni o fi eniyan sinu ara Kristi ti ise ijo Kristi, “ Nitori pe ninu Emi kan li a ti baptisi gbogbo wa sinu ara kan…” I Kor. 12:12, ti ise agbo igbala kansoso ti Olorun nyan awon eni-igbala si Ise Awo Aposteli 2:41, 47.

Eniyan ko le ni IGBALA yi bi o ba se ohun ti oba yato si Ilana ti Kristi wonyi- I Pet. 4:10, Gal. 1:8-9, Filip 4:9. Emi re wa ninu ewu bi o kuna lati se igboran si oro Olorun yi ki o to fi aye yi sile.

Se igboran si ase Kristi yi loni ki o ba le je eni igbala.

 
| Home | Media | Languages | Free Stuff | Contact Us |

Powered by Joomla 1.5.20 | Template modified by WCBC.